O. Daf 4:2-4

O. Daf 4:2-4 YBCV

Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe? Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e. Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ.