O. Daf 37:7-9

O. Daf 37:7-9 YBCV

Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ. Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu. Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye.