O. Daf 36:5-9

O. Daf 36:5-9 YBCV

Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma. Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́. Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ. Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ. Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.