O. Daf 35:1-3

O. Daf 35:1-3 YBCV

OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà. Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi. Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ.