O. Daf 34:8-14

O. Daf 34:8-14 YBCV

Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e. Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara. Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa. Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere? Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ. Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀.