O. Daf 34:4-15

O. Daf 34:4-15 YBCV

Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn. Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e. Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara. Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa. Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere? Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ. Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀. Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn.