O. Daf 34:3-8

O. Daf 34:3-8 YBCV

Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke. Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn. Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e.