O. Daf 34:15-18

O. Daf 34:15-18 YBCV

Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn. Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ. Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.