O. Daf 34:1-4

O. Daf 34:1-4 YBCV

EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke. Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi.