O. Daf 34:1-3

O. Daf 34:1-3 YBCV

EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.