O. Daf 33:6-9

O. Daf 33:6-9 YBCV

Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀. O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura. Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin.