O. Daf 33:1-3

O. Daf 33:1-3 YBCV

ẸMA yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo: nitoriti iyìn yẹ fun ẹni-diduro-ṣinṣin. Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i. Ẹ kọ orin titun si i: ẹ ma fi ọgbọngbọn lù ohun ọnà orin pẹlu ariwo.