O. Daf 32:8-11

O. Daf 32:8-11 YBCV

Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ. Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni iyè ninu: ẹnu ẹniti a kò le ṣe aifi ijanu bọ̀, ki nwọn ki o má ba sunmọ ọ. Ọ̀pọ ikãnu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle Oluwa, ãnu ni yio yi i ka kiri. Ki inu nyin ki o dùn niti Oluwa, ẹ si ma yọ̀, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin.