O. Daf 31:21-24

O. Daf 31:21-24 YBCV

Olubukún ni Oluwa; nitori ti o ti fi iṣeun-ifẹ iyanu rẹ̀ hàn mi ni ilu olodi. Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ. Ẹ fẹ Oluwa, gbogbo ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: Oluwa npa onigbagbọ́ mọ́, o si san a li ọ̀pọlọpọ fun ẹniti nṣe igberaga. Ẹ tujuka, yio si mu nyin li aiya le, gbogbo ẹnyin ti o ni ireti niti Oluwa.