O. Daf 31:2-24

O. Daf 31:2-24 YBCV

Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si. Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi. Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi. Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ. Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa. Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju; Iwọ kò si sé mi mọ́ si ọwọ ọta nì: iwọ fi ẹsẹ mi tẹlẹ ni ibi àye nla. Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi. Emi fi ibinujẹ lò ọjọ mi, ati ọdun mi ti on ti imi-ẹ̀dun: agbara mi kú nitori ẹ̀ṣẹ mi, awọn egungun mi si run. Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi. Emi ti di ẹni-igbagbe kuro ni ìye bi okú: emi dabi ohun-elo fifọ́. Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro. Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi. Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi, Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ. Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú. Awọn ète eke ni ki a mu dakẹ; ti nsọ̀rọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹ̀gan si awọn olododo. Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia! Iwọ o pa wọn mọ́ ni ibi ìkọkọ iwaju rẹ kuro ninu idimọlu awọn enia; iwọ o pa wọn mọ́ ni ìkọkọ ninu agọ kan kuro ninu ija ahọn. Olubukún ni Oluwa; nitori ti o ti fi iṣeun-ifẹ iyanu rẹ̀ hàn mi ni ilu olodi. Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ. Ẹ fẹ Oluwa, gbogbo ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: Oluwa npa onigbagbọ́ mọ́, o si san a li ọ̀pọlọpọ fun ẹniti nṣe igberaga. Ẹ tujuka, yio si mu nyin li aiya le, gbogbo ẹnyin ti o ni ireti niti Oluwa.