O. Daf 30:8-12

O. Daf 30:8-12 YBCV

Emi kigbe pè ọ, Oluwa; ati si Oluwa li emi mbẹ̀bẹ gidigidi. Ere kili o wà li ẹ̀jẹ mi, nigbati mo ba lọ sinu ihò? erupẹ ni yio ma yìn ọ bi? on ni yio ma sọ̀rọ otitọ rẹ bi? Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi. Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure. Nitori idi eyi ni ki ogo mi ki o le ma kọrin si ọ, ki o má si ṣe dakẹ. Oluwa Ọlọrun mi, emi o ma fi iyìn fun ọ lailai.