O. Daf 30:1-6

O. Daf 30:1-6 YBCV

EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi. Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da. Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho. Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀. Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ. Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai.