O. Daf 26:5-8

O. Daf 26:5-8 YBCV

Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko. Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa. Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ. Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ.