O. Daf 25:4-7

O. Daf 25:4-7 YBCV

Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ. Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo. Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ