O. Daf 25:16-20

O. Daf 25:16-20 YBCV

Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi. Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka. Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ.