O. Daf 24:3-5

O. Daf 24:3-5 YBCV

Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀? Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan. On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀.