Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ, Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli. Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́. Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai: Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀. Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède. Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye. Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa. Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi.
Kà O. Daf 22
Feti si O. Daf 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 22:22-31
7 Days
How can we find the right attitude for every situation? What is the right attitude? This seven-day Bible Plan finds answers in the life and teachings of Christ. Let these daily encouragements, reflective prayers, and powerful Scriptures form in you the mind of Christ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò