O. Daf 22:22-26

O. Daf 22:22-26 YBCV

Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ, Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli. Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́. Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai