O. Daf 19:7-13

O. Daf 19:7-13 YBCV

Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n. Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju. Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn. Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin. Pẹlupẹlu nipa wọn li a ti ṣi iranṣẹ rẹ leti; ati ni pipamọ́ wọn ere pipọ̀ mbẹ. Tali o le mọ̀ iṣina rẹ̀? wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu iṣiṣe ìkọkọ mi. Fà iranṣẹ rẹ sẹhin pẹlu kuro ninu ẹ̀ṣẹ ikugbu: máṣe jẹ ki nwọn ki o jọba lori mi: nigbana li emi o duro ṣinṣin, emi o si ṣe alaijẹbi kuro ninu ẹ̀ṣẹ nla nì.