O. Daf 19:1-3

O. Daf 19:1-3 YBCV

AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn. Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn.