O. Daf 18:46-49

O. Daf 18:46-49 YBCV

Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke. Ọlọrun li o ngbẹsan mi, ti o si nṣẹ́ awọn enia fun mi. O gbà mi lọwọ awọn ọta mi: pẹlupẹlu iwọ gbé mi leke jù awọn ti o dide si mi lọ; iwọ ti gbà mi lọwọ ọkunrin alagbara nì. Nitorina li emi ṣe fi iyìn fun ọ, Oluwa, li awujọ awọn orilẹ-ède, emi o si ma kọrin iyìn si orukọ rẹ.