O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn. Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi. Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi. Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run. Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn. Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita. Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi. Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi. Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn.
Kà O. Daf 18
Feti si O. Daf 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 18:34-45
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò