Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ, Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri. Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga. Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ: Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ. Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ: Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn. Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.
Kà O. Daf 17
Feti si O. Daf 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 17:8-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò