O. Daf 16:5-8

O. Daf 16:5-8 YBCV

Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.