O. Daf 121:1-4

O. Daf 121:1-4 YBCV

EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa? Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye. On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe. Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn.