O. Daf 119:89-93

O. Daf 119:89-93 YBCV

Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye.