O. Daf 119:81-128

O. Daf 119:81-128 YBCV

Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu? Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ. Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi? Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ. Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ. Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ. Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́. Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi. Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo. Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin. Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ. Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.