O. Daf 119:145-152

O. Daf 119:145-152 YBCV

Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.