O. Daf 119:143-176

O. Daf 119:143-176 YBCV

Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi. Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ. Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.