O. Daf 119:1-112

O. Daf 119:1-112 YBCV

IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ. Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́. Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ: Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi. Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ. Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ. Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi. Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi. Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi. Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ. Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ. Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ. Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ. Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi. Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ. Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi. Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu? Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ. Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi? Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ. Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ. Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ. Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́. Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi. Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo. Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.