O. Daf 118:1-7

O. Daf 118:1-7 YBCV

Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla. Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi.