O. Daf 116:1-8

O. Daf 116:1-8 YBCV

EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi. Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi. Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu. Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi. Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa. Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ. Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ. Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu.