Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi. Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi. Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú. Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra. Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn. Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ. Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e. Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀. Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu. Emi o ma fi ẹnu mi yìn Oluwa gidigidi; nitõtọ, emi o ma yìn i lãrin ọ̀pọ enia. Nitori ti yio duro li ọwọ ọtún olupọnju, lati gbà a lọwọ awọn ti o nda ọkàn rẹ̀ lẹbi.
Kà O. Daf 109
Feti si O. Daf 109
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 109:21-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò