Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì. O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá. Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe. Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn, O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.
Kà O. Daf 107
Feti si O. Daf 107
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 107:1-9
6 Days
Who is God? We all have different answers, but how do we know what’s true? No matter what your experiences with God, Christians, or church have been like, it’s time to discover God for who He really is—real, present, and ready to meet you right where you are. Take the first step in this 6-day Bible Plan accompanying Pastor Craig Groeschel’s message series, God Is _______.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò