O. Daf 104:33-35

O. Daf 104:33-35 YBCV

Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi. Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa. Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.