O. Daf 104:10-13

O. Daf 104:10-13 YBCV

Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun.