O. Daf 102:24-27

O. Daf 102:24-27 YBCV

Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ. Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ, Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ. Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin.