Owe 6:20-35

Owe 6:20-35 YBCV

Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ. Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ. Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye: Lati pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin buburu nì, lọwọ ahọn ìpọnni ajeji obinrin. Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara. Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona? Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀. Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run. Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro. Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan. On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ.