Owe 6:12-19

Owe 6:12-19 YBCV

Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke. O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe; Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ. Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe. Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika, Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin.