Owe 5:1-14

Owe 5:1-14 YBCV

ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi. Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́. Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ: Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji. Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú. Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀. Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.