Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́. Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run. Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta. Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́; Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba. Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn: Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan; Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀. Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ. Nitõtọ, mimì wàra ni imu orí-àmọ́ wá, ati fifun imu ni imu ẹ̀jẹ jade; bẹ̃ni riru ibinu soke ni imu ìja wá.
Kà Owe 30
Feti si Owe 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 30:24-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò