Ọ̀RỌ Aguri, ọmọ Jake, ọ̀rọ ẹkọ́ ti ọkunrin na ti sọ, fun Itieli, ani fun Itieli ati Ukali. Nitõtọ emi ṣiwère jù ẹlomiran lọ, emi kò si ni imoye enia. Emi kò tilẹ kọ́ ọgbọ́n, emi kò tilẹ ni ìmọ ohun mimọ́. Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rẹ̀? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rẹ̀ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rẹ̀ ti ijẹ, bi iwọ ba le mọ̀ ọ? Gbogbo ọ̀rọ Oluwa jẹ́ otitọ: on li asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e. Iwọ máṣe fi kún ọ̀rọ rẹ̀, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke. Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ; máṣe fi wọn dù mi ki emi to kú. Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi. Ki emi ki o má ba yó jù, ki emi ki o má si sẹ́ ọ, pe ta li Oluwa? tabi ki emi má ba tòṣi, ki emi si jale, ki emi si ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi.
Kà Owe 30
Feti si Owe 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 30:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò