Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ. Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn. Máṣe fòya ẹ̀ru ojijì, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de. Nitori Oluwa ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ninu atimu. Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e. Máṣe wi fun ẹnikeji rẹ pe, Lọ, ki o si pada wá, bi o ba si di ọla, emi o fi fun ọ; nigbati iwọ ni i li ọwọ rẹ. Máṣe gbìro buburu si ọmọnikeji rẹ, bi on ti joko laibẹ̀ru lẹba ọdọ rẹ. Máṣe ba enia jà lainidi, bi on kò ba ṣe ọ ni ibi. Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀. Nitoripe irira li ẹlẹgan loju Oluwa; ṣugbọn aṣiri rẹ̀ wà pẹlu awọn olododo. Egún Oluwa mbẹ ni ile awọn enia buburu: ṣugbọn o bukún ibujoko awọn olõtọ. Nitõtọ o ṣe ẹ̀ya si awọn ẹlẹya: ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ. Awọn ọlọgbọ́n ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn.
Kà Owe 3
Feti si Owe 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 3:23-35
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò