Owe 3:13-26

Owe 3:13-26 YBCV

Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin. Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ. Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́: Bẹ̃ni nwọn o ma jẹ ìye si ọkàn rẹ, ati ore-ọfẹ si ọrùn rẹ. Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ. Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn. Máṣe fòya ẹ̀ru ojijì, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de. Nitori Oluwa ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ninu atimu.