ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ: Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia. Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ. Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ. Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun. Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin. Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ.
Kà Owe 3
Feti si Owe 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 3:1-20
7 Days
If someone asked you, "What do I need to believe to be a Christian?" what would you say? By using the simple lyrics to a beloved song, "Jesus loves me, this I know, for the Bible tells me so”, a journalist-turned-pastor helps you understand what you believe and why. Bestselling author John S. Dickerson clearly and faithfully explains essential Christian beliefs and powerfully illustrates why these beliefs matter.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò